Ofin Ipile Ti o se Itilehin Eto Ise Ohun Elo Ero Oloye Komputa LaijafiraAwon ofin ipile ti an tele ni wonyi:

Ohun ti o je wa l'ogun julo ni wipe ki a te awon onibara wa lorun
nipa sise ohun elo ero oloye komputa ti o wulo nidede, lai dawoduro ati laijafira.

Titewo gba ibeere fun atunse ati iyipada eto ise, paapaa ni asale
ise idagba soke na. Awon igbese ise yio lo agbara iyipada won yi fun anfani ati igbesoke oro aje awon onibara wa.

Pipese awon ojulowo ohun elo ero oloye komputa lati tete de odo awon onibara wa
larin ose meji sii osu meji, ni akoko ti o kuruju, laijafira.

O se pataki fun awon onisowo ati awon ti o se agbateru ise ohun elo ero oloye komputa yi lati jo maa sise
papo lojojumo ati nigbagbogbo, jaleyika igbero ise na.

Ao se eto igbero ise yi yika awon osise fun iwuriimoriya olukuluku.
Ao fi won si ayika tio dara, ao si fun won ni atilehin ati iranlowo
lati le ni igbekele pe won yio se ise ni kiakia ati pelu iyari.

Ona ti o niyorisi ati idaniloju julo
lati fi iroyin ohun ti o nsele to awon osise ohun elo ero oloye komputa
leti ni nipa ipade ati si so oro ni ojukoro.

Osuwon ilosiwaju ti o se pataki ju ni pipese ohun elo ero oloye komputa ti o wulo.

Igbese ona ti a le fi se ise ti o joju ni ki ibasepo ni ilosiwaju.
Awon igilehin ogba nipa inawo, awon agbateru ati awon ti on lo irinse ohun elo ero oloye komputa yii gbodo maa jo sise papo ni igbagbogbo, ki ibasepo ti o dan moran bale wa ni aarin won.

Amojuto ise takun takun, imo
ati apẹrẹ ti o peye yio mu ki ise tubo ni ere lori.

O se pataki lati ri daju wipe ise aseti ati asedanu dinku.

Akojopo osise ti o le se eto lesẹsẹ ni won le mu apẹrẹ
ati ohun ti a fe jade ni ona ti o dara julo.

Loore koore, awon alajosepo yio se ayewo bi
ise won se tun le niyorisi, won awa to ise won lesẹsẹ
lati le se atunse ihuwasi ati akojopo won, bi o se to ati bi o se ye.
Pada si Ilana Eto